Ẹ́sírà 4:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe àìkọbi-ara sí ọ̀rọ̀ yìí. Èéṣe tí ìbàjẹ́ yóò fi pọ̀ sí i, sí ìpalára àwọn ọba?

23. Ní kété tí a ka ẹ̀dà ìwé ọba Aritaṣéṣéṣì sí Réhúmì àti Ṣímíṣáì akọ̀wé àti àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn, wọ́n yára lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní Jérúsálẹ́mù pẹ̀lú, wọ́n fi agbára mú wọn láti dáwọ́ dúró.

24. Báyìí, iṣẹ́ lórí ilé Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù wá sí ìdúró jẹ́ẹ́ títí di ọdún kejì ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.

Ẹ́sírà 4