1. Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”
2. Fáráò dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ.”