5. Nígbà ti Árónì rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa.”
6. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rúbọ síṣun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.
7. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Ṣọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Éjíbítì, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.
8. Wọ́n ti yára láti yípadà kúrò nínú ohun ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹ̀gbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rúbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Ísíirẹ́lì wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.’ ”
9. Olúwa wí fún Mósè pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn.