Ékísódù 26:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́ yóòkù kí o sì lò wọ́n láti fi fa àwọn aṣọ títa náà papọ̀, nítorí náà àgọ́ náà yóò jẹ́ ọ̀kan.

7. “Ṣe aṣọ títa irun ewúrẹ́ láti fi ṣe ibò sórí àgọ́ náà—kí ó jẹ́ mọ́kànlá papọ̀.

8. Gbogbo aṣọ títa mọ̀kánlà náà gbọdọ̀ jẹ́ déédé-ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀wọ́ mẹ́rin ní fífẹ̀.

9. Aṣọ títa márùn ún ni kí ó papọ̀ mọ́ ara wọn sí apá kan àti mẹ́fà tókù sí apá ọ̀tọ̀. Yí aṣọ títa kẹfà po sí méjì níwájú àgọ́ náà.

Ékísódù 26