24. Kí o fi ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì mọ wúrà yíká.
25. Bákan náà, mọ etí rẹ̀ yíká pẹ̀lú wúrà níwọ̀n fífẹ ìbúwọ́, kí o sì fi wúrà mímọ́ sí ibí orúka rẹ.
26. Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, kí o so ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mọ́ igun ẹsẹ̀ rẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
27. Òrùka náà ko gbọdọ̀ jìnnà sí etí rẹ̀, kí ó lè gbá òpó mú nígbà tí a bá ń gbé tábìlì náà.
28. Fi igi kaṣíà ṣe òpó, fi wúrà bò wọ́n, kí o sì máa fi wọ́n gbé tábìlì náà.
29. Fi ojúlówó wúrà se àwo àti ṣíbí rẹ̀, kí o sì ṣe àwokòtò àti ago pẹ̀lú fún dída ọrẹ jáde.
30. Gbé àkàrà ìfihàn sí orí tabílì yìí, kí ó le wà ní iwájú mi ni gbogbo ìgbà.