Ékísódù 18:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Mo mọ nísinsìnyìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Éjíbítì.”

12. Jẹ́tírò, àna Mósè, mú ọrẹ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Árónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì wá láti bá àna Mósè jẹun ní iwájú Ọlọ́run.

13. Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mósè fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.

Ékísódù 18