Ékísódù 15:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí Olúwa:Èmi yóò kọrin sí Olúwa,nítorí òun pọ̀ ní ògo.Ẹsin àti ẹni tí ó gùn unni ó ti sọ sínú òkun.

2. Olúwa ni agbára àti orin mi;òun ti di Olùgbàlà mi,òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín,Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.

3. Ologun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

4. Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú òkun.Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú òkun pupa.

Ékísódù 15