Ékísódù 1:11-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí náà, wọ́n yan àwọn ọ̀gá akóniṣiṣẹ́ lé wọn lórí láti máa ni wọ́n lára pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára. Wọ́n sì kọ́ Pítómi àti Ráméṣéṣì gẹ́gẹ́ bí ìlú ìkó ìṣúra pamọ́ sí fún Fáráò.

12. Ṣùgbọ́n bí a ti ń ni wọ́n lára tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń pọ̀ sí i, ti wọn sì ń tàn kálẹ̀; Nítorí náà, àwọn ará Éjíbítì bẹ̀rù nítorí àwọn ará Ísírẹ́lì.

13. Wọ́n sì mú wọn ṣiṣẹ́ àṣekú láìkáánú wọn.

14. Wọ́n mú wọn gbé ìgbé ayé kíkorò nípa iṣẹ́ ẹ bíríkì àti àwọn onírúurú iṣẹ́ oko; àwọn ará Éjíbítì ń lò wọ́n ní ìlòkulò.

15. Ọba Éjíbítì sọ fún àwọn agbẹ̀bí Hébérù ti orúkọ wọn ń jẹ́ Ṣífúrà àti Púà pé:

16. “Nígbà ti ẹ̀yin bá ń gbẹ̀bí àwọn obìnrin Hébérù, tí ẹ sì kíyèsí wọn lórí ìkúnlẹ̀ ìrọbí wọn, bí ó bá jẹ́ ọkùnrin ni ọmọ náà, ẹ pa á; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ obìnrin, ẹ jẹ́ kí ó wà láàyè.”

17. Ṣùgbọ́n àwọn agbẹ̀bí bẹ̀rù Ọlọ́run, wọn kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ọba Éjíbítì ti wí fún wọn; wọ́n jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin wà láàyè.

18. Ọba Éjíbítì pe àwọn agbẹ̀bí ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ṣe èyí?, Èéṣe tí ẹ̀yin fi dá àwọn ọmọkùnrin si?”

Ékísódù 1