13. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Mo ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pé alágídí ènìyàn gbáà ni wọ́n.
14. Fi mí sílẹ̀, jẹ́ kí n run wọ́n, kí n sì pa orúkọ wọn rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì pọ̀ jù wọ́n lọ.”
15. Báyìí ni mo yípadà, tí mó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí okè náà wá, orí òkè tí o ń yọná. Àwọn sílétì májẹ̀mú méjèèjì sì wà lọ́wọ́ mi.
16. Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un yín.
17. Bẹ́ẹ̀ ni mó ju síléètì méjèèjì náà mọ́lẹ̀, mo sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ lójú u yín.