19. Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀ta yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.
20. Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?”
21. Sọ fún un pé: “Ẹrú Fáráò ní ilẹ̀ Éjíbítì ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Éjíbítì.
22. Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Éjíbítì àti Fáráò, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀.