Deutarónómì 33:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ó kọ́ Jákọ́bù ní ìdájọ́ rẹ̀àti Ísírẹ́lì ní òfin rẹ̀.Ó mú tùràrí wá ṣíwájú rẹ̀àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.

11. Bù sí ohun ìní rẹ̀, Olúwa,kí o sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”

12. Ní ti Bẹ́ńjámínì ó wí pé:“Jẹ́ kí olùfẹ́ Olúwa máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,ẹni tí Olúwa fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrin èjìká rẹ̀.”

13. Ní ti Jóṣẹ́fù ó wí pé:“Kí Olúwa bùkún ilẹ̀ rẹ,fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrìàti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;

14. àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wáàti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;

15. pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;

16. Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀.

17. Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù,àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”

Deutarónómì 33