Deutarónómì 27:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

8. Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”

9. Nígbà náà ni Móṣè àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì, sọ fún Ísírẹ́lì pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Ísírẹ́lì, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí.

10. Gbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

11. Ní ọjọ́ kan náà Móṣè pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

Deutarónómì 27