Deutarónómì 22:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Má ṣe gbin oríṣìí èso méjì sínú ọgbà àjàrà rẹ; bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, kì í ṣe èṣo oko tí o gbìn nìkan ṣùgbọ́n èṣo ọgbà àjàrà pẹ̀lú yóò bàjẹ́.

10. Má ṣe fi akọ màlúù àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tulẹ̀ pọ̀.

11. Má ṣe wọ aṣọ onírun àgùntàn àti aṣọ funfun papọ̀.

12. Kí o ṣe wajawaja sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin aṣọ ìlẹ̀kẹ̀ rẹ.

Deutarónómì 22