Deutarónómì 17:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta ni a ó pa ọkùnrin náà tí ó yẹ láti kú, ṣùgbọ́n ẹ má ṣe pànìyàn nípaṣẹ̀ ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo.

7. Àwọn ẹlẹ́rìí ni kí ó kọ́kọ́ gbọ́wọ́ lé e láti pa á. Lẹ́yìn èyí ni kí gbogbo ènìyàn dáwọ́jọ láti pa á. Nípa báyìí, ẹ̀yin yóò sì fọ ohun búburú náà mọ́ kúrò ní àárin yín.

8. Bí ẹjọ́ bá wá sí ilé ẹjọ́ ọ yín tí ó nira jù láti dá: yálà ìtàjẹ̀sílẹ̀ ni, ọ̀ràn dídá tàbí ìkanni-lábùkù: Ẹ mú wọn lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn.

9. Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà tí í ṣe Léfì, àní sí ọ̀dọ̀ adájọ́ tí ó wà fún ìgbẹ́jọ́ ní ìgbà náà. Ẹ béèrè lọ́wọ́ wọn, wọn yóò sì ṣe ìdájọ́.

Deutarónómì 17