Deutarónómì 14:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nínú gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń gbé inú omi, ẹ lè jẹ èyíkéyí tí ó ní lẹbẹ àti ìpẹ́.

10. Ṣùgbọ́n èyíkéyí tí kò bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́, ẹ má ṣe jẹ ẹ́, nítorí pé àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún un yín.

11. Ẹ lè jẹ ẹyẹ tí ó bá mọ́.

12. Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ní ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: idì, igún, àkàlà,

13. onírúurú àṣá àti àṣá alátagbà,

Deutarónómì 14