Deutarónómì 14:22-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń fi ìdá kan nínú mẹ́wàá nínú irè oko yín lọ́dọọdún pamọ́ sí apákan

23. Ẹ jẹ ìdámẹ́wàá, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun, òróró, àti àkọ́bí àwọn màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín, níwájú Olúwa Ọlọ́run yín, ní ibi tí yóò yàn bí ibùgbé orúkọ rẹ̀. Kí ẹ lè kọ́ bí a ṣé ń bọlá fún Olúwa Ọlọ́run yín nígbà gbogbo.

24. Bí ibẹ̀ bá jìn tí Olúwa Ọlọ́run rẹ sì ti bùkún fún ọ, tí o kò sì le ru àwọn ìdámẹ́wàá rẹ (nítorí pé ibi tí Olúwa yóò yàn láti fi orúkọ rẹ̀ sí jìnnà jù).

25. Ẹ pààrọ̀ àwọn ìdámẹ́wàá yín sówó, ẹ mú owó náà lọ sí ibi tí Olúwa yóò yàn.

26. Fi owó náà ra ohunkóhun tí o bá fẹ́, màlúù, àgùntàn, wáìnì, tàbí ọtí líle, tàbí ohunkóhun tí o bá fẹ́. Kí ìwọ àti ìdílé rẹ sì jẹ ẹ́ níwájú Olúwa níbẹ̀ kí ẹ sì máa yọ̀.

27. Ẹ má ṣe gbàgbé àwọn Léfì tí ó ń gbé nì ilú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín kan tàbí ogún kan tí í se tiwọn.

Deutarónómì 14