Deutarónómì 12:4-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn.

5. Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrin àwọn ìran yín, láti fi orúkọ rẹ̀ ṣíbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ.

6. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ọrẹ síṣun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.

7. Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.

Deutarónómì 12