Dáníẹ́lì 8:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Bí ó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo ti sùn lọ fọnfọn, bí mo ṣe da ojú bolẹ̀. Nígbà náà ni ó fi ọwọ́ kàn mí, ó sì gbé mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi.

19. Ó sọ wí pé: “Èmi yóò sọ ohun tí yóò sẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ní ìgbà ìbínú, nítorí ìran náà jẹ mọ́ àkókò ohun tí a yàn nígbà ìkẹyìn.

20. Àgbò oníwo méjì tí o rí, òun ni ó dúró gẹ́gẹ́ bí àwọn ọba Médíánì àti Páṣíà.

21. Òbúkọ onírun náà ni ọba Gíríkì, ìwo ńlá ti ó wà láàrin ojú u rẹ̀ ni ọba àkọ́kọ́.

22. Ìwo mẹ́rin ti ó dípo ọ̀kan tí ó kán dúró, èyí dúró gẹ́gẹ́ bí ìjọba mẹ́rin tí ó dìde láti orílẹ̀ èdè e rẹ̀ ṣùgbọ́n wọn kò ní ní irú agbára kan náà.

Dáníẹ́lì 8