Dáníẹ́lì 8:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Beliṣáṣárì ọba, èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.

2. Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Súsáni ní agbègbè ìjọba Élámù: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Úláì.

Dáníẹ́lì 8