16. Nígbà náà, ni ọba pàṣẹ, wọ́n sì mú Dáníẹ́lì, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò kìnnìún. Ọba sì sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Kí Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn nígbà gbogbo kí ó gbà ọ́!”
17. A sì gbé òkúta kan wá, wọ́n sì fi dí ẹnu ihò náà, ọba sì dí i pa pẹ̀lú òrùka èdìdì rẹ̀ àti pẹ̀lú òrùka àwọn ọlọ́lá rẹ̀, nítorí kí a má ṣe yí ohunkóhun padà nítorí i Dáníẹ́lì.
18. Nígbà náà ni ọba padà sí ààfin rẹ̀, ó sì lo gbogbo òru náà láì jẹun, kò sì gbọ orin kankan, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le è ṣùn ní òru ọjọ́ náà.
19. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù, ni ọba dìde ó sì sáré lọ sí ibi ihò kìnnìún náà.
20. Nígbà tí ó sún mọ́ ibi ihò náà ní ibi tí Dáníẹ́lì wà, ó pe Dáníẹ́lì pẹ̀lú ìtara pé, “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, ṣé Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn tọ̀sán tòru, lè gbà ọ́ lọ́wọ́ ọ kìnnìún bí?”