Dáníẹ́lì 2:48-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Nígbà náà ni ọba gbé Dáníẹ́lì ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Bábílónì àti olórí gbogbo àwọn amòye Bábílónì.

49. Dáníẹ́lì béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Sádírákì, Mésákì, àti Àbẹ́dinígò gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbéríko Bábílónì ṣùgbọ́n Dáníẹ́lì fún ra rẹ̀ wà ní ààfin ọba.

Dáníẹ́lì 2