1. Ní ọdún kẹta Sárúsì ọba Páṣíà, a fi ìran kan hàn Dáníẹ́lì (ẹni tí à ń pè ní Bélítésásárì). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran.
2. Ní àsìkò náà, èmi Dáníẹ́lì ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta.
3. Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.