Àwọn Hébérù 7:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni Jésù ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.

23. Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.

24. Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ nípò.

25. Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nipasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láàyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.

Àwọn Hébérù 7