Àwọn Hébérù 10:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Kí a ma máa kọ ìpejọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni niyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ etílé.

26. Nítorí bí àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́sẹ̀ lẹ̀yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

27. Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ní lẹ̀rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀ta run.

28. Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Móṣè, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta:

29. Mélòómélòó ni ẹ rò pé a o jẹ Olúwa rẹ̀ ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹgan ẹmi oore òfẹ́.

Àwọn Hébérù 10