Ámósì 8:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí ń tẹ aláìní lórí ba,tí ẹ sì ń sọ talákà di ilẹ

5. Tí ẹ ń wí pé,“Nígbà wo ni oṣù tuntun yóò paríkí àwa bá à lè ta ọkàkí ọjọ́ ìsinmi kí ó lè dópinkí àwa bá à le ta jéró?”Kí a sì dín ìwọ̀n wa kùkí a gbéraga lórí iye tí a ó tà ákí a sì fi òṣùnwọ̀n èké yàn wọ́n jẹ

6. Kí àwa lè fi fàdákà ra àwọn talákàkí a sì fi bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì ra aláìníkí a sì ta jéró tí a kó mọ́ ilẹ̀

Ámósì 8