9. “Ibi gíga Ísáákì wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoroàti ibi mímọ Ísírẹ́lì wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.Èmi yóò sì fi idà dide sí ilé Jéróbóámù.”
10. Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé: “Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.
11. Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ:“ ‘Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú,Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn,jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”
12. Nígbà náà ni Ámásáyà sọ fún Ámósì pé “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Júdà. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀ ki o sì sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.
13. Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Bẹ́tẹ́lì nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹ́ḿpìlì ìjọba rẹ̀.”
14. Ámósì dá Ámásáyà lóhùn pé, “Èmi kì í ṣe wòlíì tàbí àwọn ọmọ wòlíì, ṣùgbọ́n mo jẹ́ olùsọ́-àgùntàn, mo sì ń ṣe ìtọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.
15. Ṣùgbọ́n Olúwa mu mi bí mo ti ń tọ́ agbo ẹran lẹ́yìn, ó sì wí fun mi pé, ‘Lọ sọtẹ́tẹ̀ fun àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi.’