Ámósì 4:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Mo ti bì ṣubú nínú yín,bí Ọlọ́run ti bi Sódómù àti Gòmórà ṣubúẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fò yọ kúrò nínú ìjóná,ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”ni Olúwa wí.

12. “Nítorí náà, èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí i yín, Ísírẹ́lì,àti nítorí tí èmi ó ṣe èyí sí i yín,ẹ múra láti pàdé Ọlọ́run yín, ẹ̀yin Ísírẹ́lì.”

13. Ẹni tí ó dá àwọn òkètí ó dá afẹ́fẹ́tí ó sì fi èrò rẹ̀ hàn sí ènìyàn,ẹni tí ó yípadà sí òkùnkùntí ó sì tẹ ibi gíga ayé. Olúwa Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ni orúkọ rẹ̀.

Ámósì 4