2. Báyìí, a sọ fún ilé Dáfídì pé, “Árámù mà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfáímù”; fún ìdí èyí, ọkàn Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ wárìrì gẹ́gẹ́ bí igi oko ṣe ń wárìrì níwájú afẹ́fẹ́.
3. Lẹ́yìn èyí, Olúwa sọ fún Àìṣáyà pé, “Jáde, ìwọ àti ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ Ṣéárì-Jáṣúbù láti pàdé Áhásì ní ìpẹ̀kun ìṣàn-omi ti adágún òkè, ní òpópó ọ̀nà tí ó lọ sí pápá Alágbàfọ̀.
4. Sọ fún un, ‘Ṣọ́ra à rẹ, fi ọkàn balẹ̀, kí o má ṣe bẹ̀rù. Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítoríi kùkùté igi ìdáná méjèèjì yìí, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Árámù àti ti ọmọ Rẹ̀málíà.
5. Árámù, Éfáímù àti Rèmálíà ti dìtẹ̀ ìparun rẹ, wọ́n wí pé,