5. Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún miàti ìrunú mi ni ó gbémiró.
6. Mo tẹ orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mumo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”
7. Èmi yóò sọ nípa àánú Olúwaìṣe rẹ gbogbo tí ó yẹ kí a yìn ín fún,gẹ́gẹ́ bí ohun tí Olúwa ti ṣe fún wabẹ́ẹ̀ ni, ohun rere gbogbo tí ó ti ṣefún ilé Ísírẹ́lìgẹ́gẹ́ bí àánú àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore rẹ̀.
8. Ó wí pé, “Lótítọ́ ènìyàn mi ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kì yóò jẹ́ òpùrọ́ fún mi”;bẹ́ẹ̀ ni, ó sì di Olùgbàlà wọn.
9. Nínú un gbogbo ìpọ́njúu wọn, inú òun pẹ̀lú bàjẹ́àti ańgẹ́lì tí ó wà níwájú rẹ̀ gbà wọ́n là.Nínú Ìfẹ́ àti àánú rẹ̀, ó rà wọ́n padà;ó gbé wọn ṣókè ó sì pọ̀n wọ́nní gbogbo ọjọ́ ìgbà n nì.