Àìsáyà 59:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.

2. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojúu rẹ̀ pamọ́ fún un yíntó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.

3. Nítorí ọwọ́ọ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,àti ìka ọwọ́ọ yín fún ẹ̀bi.Ètèe yín ń pa irọ́ púpọ̀,ahọ́n an yín sì ń ṣọ̀rọ̀ nǹkan ibi.

Àìsáyà 59