Àìsáyà 51:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nínú gbogbo ọmọ tí ó bíkò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ sọ́nànínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.

19. Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—ta ni yóò tù ọ́ nínú?Ìparun àti Ìdahoro, ìyàn àti idàta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?

20. Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,gẹ́gẹ́ bí ẹtu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.Ìbínú Olúwa ti kún inú un wọn fọ́fọ́ọ́fọ́àti ìbáwí Ọlọ́run yín.

21. Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì

Àìsáyà 51