1. “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodoàti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jádeàti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
2. ẹ wo Ábúráhámù baba yín,àti Ṣérà, ẹni tó bí i yín.Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,Èmi sì bùkún un, mo sì sọ́ọ́ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3. Dájúdájú, Olúwa yóò tu Ṣíhónì nínúyóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Ídẹ́nì,gbogbo ìgbòrò rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.Ayọ̀ àti inúdídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.