Àìsáyà 37:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ǹjẹ́ àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn baba ńlá mi parun ha gbà wọ́n sílẹ̀ bí àwọn òrìṣà Gósénì, Háránì, Résípì àti àwọn ènìyàn Ẹ́dẹ́nì tí wọ́n wà ní ìlú Áṣárì?

13. Níbo ni ọba Hámátì wà, ọba Ápádì, ọba Ìlú Ṣefáfíámù tàbí Hénà tàbí Ífà?”

14. Heṣekáyà gba ìwé náà lọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ ó sì kà á. Lẹ́yìn náà ni ó gòkè lọ sí tẹ́ḿpìlì Olúwa ó sì tẹ́ ìwé náà sílẹ̀ níwájú Olúwa.

15. Heṣekáyà sì gbàdúrà sí Olúwa:

Àìsáyà 37