Àìsáyà 33:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀ èdè fọ́nká.

4. Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀ èdè ni a kórègẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn bọ́ lù ú.

5. A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;Òun yóò kún Ṣíhónì pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.

6. Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

Àìsáyà 33