Àìsáyà 30:17-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ẹgbẹ̀rún yóò sánípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn úngbogbo yín lẹ ó ṣálọ,tí a ó fi yín sílẹ̀àti gẹ́gẹ́ bí igi àṣíá ní orí òkè,gẹ́gẹ́ bí àṣíá lórí òkè.”

18. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ síjú àánú wò ọ́;ó dìde láti ṣàánú fún ọ.Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!

19. Ẹ̀yin ènìyàn Ṣíhónì, tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù, ìwọ kì yóò ṣunkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn.

Àìsáyà 30