7. Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́júÌwọ adúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nààwọn olódodo kúnná.
8. Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹàwa dúró dè ọ́;orúkọọ rẹ àti òkìkíì rẹàwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́.
9. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru;ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ.Nígbà tí ìdájọ́ọ̀ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayéàwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.
10. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi oore-ọ̀fẹ́ hàn sí àwọn ìkàwọn kò kọ́ láti ṣòdodo;kódà ní ilẹ̀ àwọn tí ó dúró ṣinṣin wọ́ntẹ̀ṣíwájú láti máa ṣe ibiwọn kò sì ka ọlá ńlá Olúwa sí.