Àìsáyà 20:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kúṣì tí wọ́n sì ń fi Éjíbítì yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n.

6. Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbọ́kànlé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Ásíríà! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”

Àìsáyà 20