5. Wá, ẹ̀yìn ará ilée Jákọ́bùẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.Ọjọ́ Olúwa.
6. Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,ìwọ ilé Jákọ́bù.Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ó ti ìlà oòrùn wá,wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Fílístínìwọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà
7. Ilẹ̀ wọ́n kún fún fàdákà àti wúràìṣúra wọn kò sì ní òpin.Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
8. Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ọwọ́ ara wọn,èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tikálára wọn ti ṣe.
9. Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,má ṣe dáríjìn wọ́n.