Àìsáyà 16:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nígbà tí Móábù farahàn ní ibi gíga rẹ̀,ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúràòfo ni ó já sí.

13. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Móábù.

14. Ṣùgbọn ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrin ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, Ògo Móábù àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó ṣálà nínú un rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

Àìsáyà 16