2 Tímótíù 2:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ìránsẹ́, Olúwa kò sì gbọdọ̀ jà; bí kò ṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù.

25. Ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn alátakò pẹ̀lú ìwà tútù, ní ìrèti pé Ọlọ́run lè fún wọn ní ìrònúpìwàdà sí ìmọ̀ òtìtọ́,

26. wọn ó sì lè bọ́ kúrò nínú ìdèkùn èṣù, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti mú wọn láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.

2 Tímótíù 2