5. Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín sọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kírísítì.
6. Ní orúkọ Jésù Kirisítì Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún-un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa.
7. Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa farawé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín.
8. Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣisẹ́ tọ̀sán-tòru kí a má baà di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.
9. Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti bèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.