2 Sámúẹ́lì 8:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe, lẹ́yìn èyí, Dáfídì sì kọlu àwọn Fílístínì, ó sì tẹrí wọn ba: Dáfídì sì gba Metegamímà lọ́wọ́ àwọn Fílístínì.

2. Ó sì kọlu Móábù, ó sì fi okùn títa kan dìwọ́n, ó sì dá wọn dùbúlẹ̀; ó sì ṣe òṣùwọ̀n okùn méjì ni iye àwọn tí yóò dá sí. Àwọn ará Móábù sì ń sin Dáfídì, wọn a sì máa mú ẹ̀bùn wá.

3. Dáfídì sì kọlu Hadadésérì ọmọ Rehóbù, ọba Sóbà, bí òun sì ti ń lọ láti mú agbára rẹ̀ bọ̀ sípò ni odò Éfúrétì.

2 Sámúẹ́lì 8