1. Ó sì ṣe, nígbà tí ọba ń gbé ní ilé rẹ̀, tí Olúwa sì fún un ní ìsinmi yíká kiri kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.
2. Ọba sì wí fún Nátánì wòlíì pé, “Sá wò ó: èmi ń gbé inú ilẹ̀ tí a fi kédárì kọ́, ṣùgbọ́n àpótí-ẹ̀rí Ọlọ́run ń gbé inú ibi tí a fi aṣọ gé.”
3. Nátanì sì wí fún ọba pé, “Lọ, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí ó wà ní ọkàn rẹ, nítorí pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.”
4. Ó sì ṣe ní òru náà, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Nátánì wá pé:
5. “Lọ, sọ fún ìránṣẹ́ mi, fún Dáfídì, pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ó ha kọ́ ilé fún mi tí èmi yóò gbé.