2 Sámúẹ́lì 22:8-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Ilẹ̀ sì mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ ọ̀run wárìrì,ó sì mì, nítorí tí ó bínú.

9. Èéfín sì jáde láti ihò-imú rẹ̀ wá;iná láti ẹnu rẹ̀ wá,ó sì ń jónirun, ẹ̀yín sì ń ràn nípasẹ rẹ̀.

10. Ó tẹ orí ọ̀run ba pẹ̀lú, ó sì sọ̀kalẹ̀;òkùnkùn biribiri sì ń bẹ ní àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀.

11. Ó sì gun orí kérúbù, ó sì fò:a sì rí i lórí ìyẹ́ afẹ́fẹ́.

12. Ó sì fi òkùnkùn ṣe ibùjókòó yí ara rẹ̀, àti àgbájọ omi,àní ìsúdudu ìkùukùu àwọ̀n sánmà.

13. Nípaṣẹ̀ ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ̀ẹ̀yín-iná ràn.

14. Olúwa sán ààrá láti ọ̀run wá,ọ̀gá ogo jùlọ sì fọhùn rẹ̀.

15. Ó sì ta ọfà, ó sì tú wọn ká;ó kọ mànàmànà, ó sì ṣẹ́ wọn.

16. Ìṣàn ibú òkun sì fi ara hàn,ìpìlẹ̀ ayé fi ara hàn,nípa ìbáwí Olúwa,nípa fífún èémí ihò imú rẹ̀.

2 Sámúẹ́lì 22