2 Sámúẹ́lì 22:37-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi;tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.

38. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.

39. Èmi ti pa wọ́n run, èmi sì ti fọ́ wọn,wọn kò sì le dìde mọ́: wọ́n ṣubú lábẹ́ mi.

40. Ìwọ sì ti fi agbára dì mí ní àmùrè fún ìjà;àwọn tí ó ti dìde sí mi ni ìwọ sì ti tẹ̀ lórí ba fún mi.

2 Sámúẹ́lì 22