2 Sámúẹ́lì 22:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. “Olúwa sán án fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi;ó sì san án fún mi gẹ́gẹ́ bí mímọ́ ọwọ́ mi.

22. Nítorí pé èmi pa ọ̀nà Olúwa mọ́,èmi kò sì fi ìwà búburú yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

23. Nítorí pé gbogbo ìdájọ́ rẹ̀ ni ó wà níwájú mi;àti ní ti òfin rẹ̀, èmi kò sì yapa kúrò nínú wọn.

24. Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í,èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.

2 Sámúẹ́lì 22