2 Sámúẹ́lì 21:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ìjà kan sì tún wà ní Gátì, ọkùnrin kan sì wà tí ó ga púpọ̀, ó sì ní ìka mẹ́fà ní ọwọ́ kan, àti ọmọ ẹṣẹ̀ mẹ́fà ní ẹṣẹ̀ kan, àpapọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ mẹ́rìnlélógún; a sì bí òun náà ní òmìrán.

21. Nígbà tí òun sì pe Ísírẹ́lì ní ìjà. Jónátanì ọmọ Ṣíméhì arákùnrin Dáfídì sì pa á.

22. Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ni a bí ní òmìrán ní Gátì, wọ́n sì ti ọwọ́ Dáfídì ṣubú àti ọwọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.

2 Sámúẹ́lì 21