9. Ábíṣáì ọmọ Serúià sì wí fún ọba pé, “Èéṣe tí òkú ajá yìí fi ń bú Olúwa mi ọba? Jẹ́ kí èmi kọjá, èmi bẹ̀ ọ́, kí èmi sì bẹ́ ẹ́ lórí.”
10. Ọba sì wí pé, “Kín ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yín ọmọ́ Séríià? Bí ó bá ń bú èébú, nítorí tí Olúwa ti wí fún un pé: ‘Bú Dáfídì!’ Ta ni yóò sì wí pé, ‘kín ni ìdí tí o fi ṣe bẹ́ẹ̀.’ ”
11. Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì, àti fún gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Wò ó, ọmọ mi tí ó ti inú mi wá, ń wá mi kiri: ǹjẹ́ mélòó mélòó ni ará Bẹ́ńjámínì yìí yóò sì ṣe? Fi í sílẹ̀, sì jẹ́ kí o máa yan èébú; nítorí pé Olúwa ni ó sọ fún un.