3. Ọba sì wí pé, “Ọmọ olúwa rẹ dà?”Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, ó jókòó ní Jérúsálẹ́mù; nítorí tí ó wí pé, ‘Lónìí ni ìdílé Ísírẹ́lì yóò mú ìjọba baba mi padà wá fún mi.’ ”
4. Ọba sì wí fún Síbà pé, “Wò ó, gbogbo nǹkan tí í ṣe ti Mefíbóṣétì jẹ́ tìrẹ.”Ṣíbà sì wí pé, “Mo túúbá, jẹ́ kí n rí ore-ọ̀fẹ́ lójú rẹ, Olúwa mi ọba.”
5. Dáfídì ọba sì dé Bahúrímù, sì wò ó, Ọkùnrin kan ti ibẹ̀ jáde wá, láti ìdílé Ṣọ́ọ̀lù wá, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣíméhì, ọmọ Gérà: ó sì ń bú èébú bí o tí ń bọ̀.