12. Bóyá Ọlọ́run yóò wo ìpọ̀njú mi, Olúwa yóò sì fi ire san án fún mi ní ipò èébú rẹ̀ lónìí.”
13. Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń lọ ní ọ̀nà, Ṣíméhì sì ń rìn lẹ́bá òkè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì ń yan èébú bí ó ti ń lọ, ó sì ń sọ ọ́ lókúta, ó sì ń fọ́n erùpẹ̀.
14. Ọba, àti gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ sì dé Jódánì, ó sì rẹ̀ wọ́n, wọ́n sì sinmi níbẹ̀.
15. Ábúsálómù àti gbogbo àwọn ènìyàn, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì sì wá sí Jérúsálẹ́mù, Áhítófélì sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
16. Ó sì ṣe, nígbà tí Húṣáì ará Áríkì, ọ̀rẹ́ Dáfídì tọ Ábúsálómù wá, Húṣáì sì wí fún Ábúsálómù pé, “Kí ọba ó pẹ́! Kí ọba ó pẹ́.”
17. Ábúsálómù sì wí fún Húṣáì pé, “Oore rẹ sí ọ̀rẹ́ rẹ ni èyí? Èéṣe tí ìwọ kò bá ọ̀rẹ́ rẹ lọ?”